[go: nahoru, domu]

Jump to content

Iyabo Ojo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Iyabo Ojo
Ìbí21 Oṣù Kejìlá 1977 (1977-12-21) (ọmọ ọdún 46)
Lagos State, Nigeria
Iṣẹ́
  • Actress
  • Film director
  • Film producer

Ìyábọ́ Alice Òjó (tí a bí ní Ọjọ́ kọnkànlélógún oṣù Kejìlá ọdún 1977)jẹ́ òṣèrébìnrin àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré tó ti kópa nínú sinimá àgbéléwò tí ó tó àádọ́jọ. Òun náà sì ti ṣe olóòtú sinimá àgbéléwò tó tó mẹ́rìnlá. [1]

Ìgbà èwe àti bí ó ṣe kẹ́kọ̀ọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, wọ́n bí Ìyábọ́ Òjó lọ́jọ́ kọnkànlélógún oṣù Kejìlá ọdún 1977. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn ni bàbá rẹ̀, Ìlú Èkó ni wọ́n bí i sí. Ó kàwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní Gbàgágà nílùú Èkó, ó kàwé ní National College ní Gbàgágà kó tó tẹ̀ síwájú ní ní ilé ìwé gíga Polí ti ìpínlẹ̀ Èkó, Lagos State Polytechnic níbi tí ó ti gboyè nínú imọ̀ ètò ìkọlé, (Estate Management)[2]

Akitiyan rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìyábọ́ Òjó tí kópa nínú sinimá àgbéléwò tó tó àádọ́jọ. Láti ìgbà èwe rẹ̀, pàápàá jùlọ ní ilé ẹ̀kọ́. Lọ́dún 1998 ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà ní ṣàn-án. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan, Bím̀bọ́ Akíntọ̀lá ló ràn án lọ́wọ́ láti dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré tíátà, (the Actors Guild of Nigeria). Ìyábọ́ Òjó kì í ṣe òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò èdè Yorùbá nìkan, ó máa ń kópa nínú sinimá àgbéléwò ti èdè òyìnbó bákan náà. Lọ́dún 1998, ó kópa nínú eré èdè òyìnbó kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Satanic". "Baba Dáríjìnwọ́n" ni sinimá àgbéléwò rẹ̀ àkókò lédè Yorùbá lọ́dún 2002. Lẹ́yìn èyí, ó ti kópa nínú sinimá àgbéléwò tó pọ̀ súa. Ìyábọ́ Òjó tí lọ́kọ, ó sìn tí sabiyamọ. [3] [4] [5]

Àtòjọ àwọn eré tó ti ṣe

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Satanic (1998)
  • Agogo Ide (1998)
  • Baba Darinjinwon (2002)
  • Okanla (2013)
  • Silence (2015)
  • Beyond Disability (2015)
  • Black Val[6]
  • Arinzo
  • Apo Owo
  • Awusa (2016)
  • Tore Ife (Love)[7]
  • Trust (2016)[7]
  • Ore (2016)
  • Ipadabo (2016)[7]
  • Twisted Twin (2016)
  • Kostrobu (2017)
  • Gone to America (2017)
  • Divorce Not Allowed (2018)
  • The Real Housewives of Lagos (2022)

Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Year Award ceremony Category Film Result Ref
2017 Best of Nollywood Awards Best Supporting Actress –Yoruba style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé [8]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Iyabo Ojo Biography and Net Worth - Austine Media". Austine Media. 2018-04-13. Retrieved 2019-11-26. 
  2. "Òótọ́ ni Iyabo Ojo ń sọ́! Ìdójútì gbàá ni kí Òṣèré máa tọrọ owó tórí àìsàn - Femi Adebayo". BBC News Yorùbá (in Èdè Latini). 2019-10-08. Retrieved 2019-11-26. 
  3. "Photos from actress' daughter's sweet 16 party". Pulse Nigeria. 2017-03-13. Retrieved 2019-11-26. 
  4. Okogba, Emmanuel; Okogba, Emmanuel (2019-06-09). "Iyabo Ojo debunks rumours she never married, releases marriage photos..". Vanguard News. Retrieved 2019-11-26. 
  5. "Iyabo Ojo’s daughter becomes brand ambassador - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2019-06-22. Retrieved 2019-11-26. 
  6. Chidumga Izuzu (15 February 2016). "'Black Val' – Toyin Aimakhu, Iyabo Ojo, Dayo Amusa, Desmond Elliott attend premiere". Pulse.ng. Chidumga Izuzu. Retrieved 16 February 2016. 
  7. 7.0 7.1 7.2 "Best Iyabo Ojo Movies 2017 | Latest Movies & Filmography" (in en-US). Yoruba Movies. Archived from the original on 25 July 2018. https://web.archive.org/web/20180725063502/http://yorubamovies.com.ng/iyabo-ojo-movies. 
  8. "BON Awards 2017: Kannywood’s Ali Nuhu receives Special Recognition Award". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-11-23. Retrieved 2021-10-07.